Location via proxy:   [ UP ]  
[Report a bug]   [Manage cookies]                
Jump to content

Gac

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Taxonomy not available for Momordica; please create it automated assistant
Gấc
Exterior and cross-sectional interior of gac
Ìṣètò onísáyẹ́nsì [ edit ]
Irú:
Template:Taxonomy/MomordicaM. cochinchinensis
Ìfúnlórúkọ méjì
Template:Taxonomy/MomordicaMomordica cochinchinensis

Gấc [IPA ɣək̚˧˦] (Momordica cochinchinensis) jẹ́ ẹ̀gúsí tó máa ń hù káàkiri apá Gúúsù mọ́ Ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asia àti àwọn orílẹ̀-èdè ní apá Àríwá mọ́ Ìlà-oòrùn Australia. Gấc gbajúmọ̀ fún àwọ̀ pupà rẹ̀ tó jọ olómi ọsàn, tó sì tún pọ̀ nínú àwọn ohun aṣaralóore bí i beta-carotene àti lycopene.

Bí orúkọ rẹ̀ ṣe wáyé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí gấc ṣe wá láti Vietnam, ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Vietnam gan-an. Wọ́n tún máa ń pe èso náà ní trái gấc or quả gấc gẹ́gẹ́ bí i trái tàbí quả tó túnmọ̀ sí 'èso' ní èdè Vietnam. Àwọn orúkọ Gẹ̀ẹ́sì mìíràn ni giant spine gourd àti sweet gourd.[1]

Orúkọ sáyẹ́ǹsì rẹ̀ tí ń ṣe cochinchinensis jẹ yọ láti agbègbè Cochinchina ní apá Gúúsù ilẹ̀ Vietnam, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n máa ń jẹ ẹ́ káàkiri ayé.[2]

Sprengel ṣàwárí pé ohun ọ̀gbìn yìí wá láti ìdílé Linnean genus Momordica ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà ní ọdún 1826.[3]

Gấc máa ń hù gẹ́gẹ́ bí i igi àjàrà dioecious, èyí tó túnmọ̀ sí pé òdòdó akọ àti abo rẹ̀ wà lára igi ọ̀tọ̀tọ̀tọ̀, tí wọ́n sì máa ń so èso tó gùn níwọ̀n. Òdòdó rẹ̀ sì máa ń jáde lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láàárín oṣù méjì sí mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n bá gbìn ín. Láàárín àsìkò kan, ó lè so ès tó tó ọgbọ̀n sí ọgọ́ta.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Taxon: Momordica cochinchinensis (Lour.) Spreng. U.S. National Plant Germplasm System.". Retrieved 2018-11-26. 
  2. Vuong, Le Thuy; Franke, Adrian A.; Custer, Laurie J.; Murphy, Suzanne P. (2006-09-01). "Momordica cochinchinensis Spreng. (gac) fruit carotenoids reevaluated" (in en). Journal of Food Composition and Analysis 19 (6–7): 664–668. doi:10.1016/j.jfca.2005.02.001. ISSN 0889-1575. 
  3. Vuong, Le (2000). "Underutilized β-Carotene–Rich Crops of Vietnam". Food and Nutrition Bulletin 21 (2): 173–181. doi:10.1177/156482650002100211. 
  4. Osman, Mohamad; Sulaiman, Zulkefly; Saleh, Ghizan et al. (2017). "Gac fruit, a plant genetic resource with high potential.". Transactions of Persatuan Genetik Malaysia 7. https://www.researchgate.net/publication/323846407.