Location via proxy:   [ UP ]  
[Report a bug]   [Manage cookies]                
Jump to content

Naples

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
NAPLES

Ìlú kan tí ó ṣe pàtàkì nínú ìtàn ni Naples. Gúsù ilẹ̀ Italy ni Naples wà. Àwọn ènìyàn tó ń gbé ibẹ̀ tó 1,278.000. Òun ni ìlú tí ó tóbi ṣe ẹ̀kẹ́ta ní ilẹ̀ Italy. Ó tẹ̀lé Rome àti Milan.

Àwọ́n ènìyàn, máa ń rin ìrìnàjò afẹ́ lọ sí ìlú yìí. Wọ́n máa ń kan ọkọ̀ ojú omi ńlá níbẹ̀. Wọ́n ní àwọn èso wọ́n sì ní àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ń sọ epo dọ̀tun.

Àwọn Greek ni ó dá Naples sílẹ̀ ṣùgbọ́n ó bọ́ sí abẹ́ àṣẹ Róòmù ní sẹ́ńtúrì kẹ́rin ṣáájú ìbí Kírísítì. Ó dá dúró funra rẹ̀ ní sẹ́ńtúrì kẹ́jọ lẹ́yìn ikú olúwa wa. Lẹ́yìn èyí ni ó wá di olú-ìlú fún ìjọba Sialy àti Naples. Naples dara pọ̀ mọ́ Italy ní 1861.